Ìmọ̀ nípa ẹ̀jẹ̀ ríru.
Ìtumọ̀ àwọn nọmba ẹ̀rọ ìfúnpá.
-
Nọmba àkọ́kọ́ dúró fún ìfúnpá sistoliki (systolic blood pressure) tàbí ìwọ̀n ríru ẹ̀jẹ̀ ní àwọn ìgbà ti ọkàn ba únlù. Èyí ni o tóbi jù nìnù àwọn nọmba méjì fun àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ ríru.
-
Nọmba kejì, ti ìsàlẹ̀, ni ìfúnpá diastoliki (diastolic blood pressure) tàbí ìwọ̀n ríru ẹ̀jẹ̀ ní àárín ọkàn lílù.
-
Ìfúnpá t’ó ṣe dédé ni sistoliki t’ó kéré ju 120 (ọgọ́fà) ati diastoliki t’ó kéré ju 80 (ọgọ́rin).
-
Aisan ẹ̀jẹ̀ ríru túmọ̀ si ìfúnpá sistoliki 130 (àádòje) àti jùbẹ́ lọ tàbí diastoliki 80 àti jùbẹ́ lọ.
Tètè rí dókítà rẹ fún àyẹ̀wò àti ìtọ́jú ẹ̀jẹ̀ ríru.
-
Joko si ori àga onítẹlọ́rùn ki o si fi ẹsẹ̀ tẹ’lẹ̀.
-
Wọ ìbọpá ẹ̀rọ ìfúnpá si apà ọ̀tún tàbí òsì kó se dédé pẹ̀lù àyè ọkàn.
-
Ṣàtúnṣe ìbọpá ki ó mọ́ra pẹ̀lu apa láì fa ìnira.
-
Tan ẹ̀rọ ìfúnpá láti bẹ̀rẹ̀ àyẹ̀wò.
Àwọn ipele ọ̀nà ẹ̀tọ́ láti ṣe ìbẹ̀wò ìfúnpá rẹ.
Àwọn okùnfà ẹ̀jẹ̀ ríru tí a lè túnṣe.
Jọ̀wọ́ lo àwọn òògùn rẹ dédé kí o si rí dókítà rẹ láti ìgbà dé ìgbà. Bá dókítà rẹ sọ̀rọ̀ kí o tó lo òògùn tuntun, ti òyìnbó tàbí ìbílẹ̀.
Àwọn okùnfà ẹ̀jẹ̀ ríru tí kò ní àtúnṣe.
*Àwọn ewu ẹ̀jẹ̀ rìru.
Ewu únlá ni ẹ̀jẹ̀ ríru fún gbogbo ẹ̀yà ara. Ní pàtàkì jùlọ:
Ọpọlọ: Àrùn rọpá-rọsẹ̀ tàbí stroke jẹ́ ìkan lára àwọn ìjàmbá ọpọlọ tí ó le ṣẹlẹ̀ nítorí ẹ̀jẹ̀ ríru tí a kò bá tọ́jú.
Ojú: Àìríran dédé àti Ìfọ́jú.
Ọkàn: Ìkùnà ọkàn (heart failure) àti ìgbókìtì ọkàn (heart attack) únfa ikú òjijì.
Kíndìnrín: Àìsàn kíndìnrín.
Àìlè gbéra pẹ́pẹ́.
Iṣọn-ẹ̀jẹ̀: Líle koko àwọn iṣọn-ẹ̀jẹ̀ ara.
*Ewu àwọn ìjàmbá yi ga lọ́pọ̀lọ́pọ̀ si fún éníyán t’ó ní àrùn ṣúgà pẹlu ẹ̀jẹ̀ ríru.