Kíni ìwọ̀n ṣúgà ẹ̀jẹ̀ rẹ?
Kini àrùn àtọ̀gbẹ tabi àrùn ṣúgà?
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ awọn oúnjẹ tí a únjẹ ni ikùn únyí padà sí glúkóósì (glucose). Glukoosi jẹ́ epo tí ara nílò fún agbára àti àwọn iṣẹ́ ṣíṣe déédé. Àìtó tàbí àìsí insulínì (insulin) únyọrísí àpọ̀jù glukoosi nínú ara tàbí arun atọgbẹ pẹ̀lú àwọn àìlera búburú t’ó somọ.
Insulini jẹ́ hòmónù (hormone) tí ó jáde nínú ẹ̀yà ikùn pancreas àti pé iṣẹ́ àkọ́kọ́ rẹ̀ ni láti jẹ́ kí glukoosi inú ẹjẹ wà fún lílò gbogbo àwọn ẹ̀yà ara.
Kò sí ìtìjú ní níní àìsàn yí àti pé o lè gbé ìgbésí ayé gìgùn nínú ìlera nípa ìsowọ́pọ̀ pẹ̀lú dókítà rẹ, jíjẹ oúnjẹ tó dára, ṣíṣe eré ìdárayá, ati lílo oògùn rẹ déédé.
Àrùn àtọ̀gbẹ oríṣi oókan (Type 1 diabetes).
Arun yí lè wáyé ní gbogbo ọjọ́ orí àti ìwọ̀n. Nínú irú àrùn àtọ̀gbẹ oókan, ara kò ní ìpèsè insulini. Àwọn ènìyàn tí ó ní àrùn yí nílò abẹ́rẹ́ insulini fún láíláí.
Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, àwọn àmì àìsàn yí máa únwáyé lójijì.
Àrùn àtọ̀gbẹ oríṣi kejì (Type 2 diabetes).
Èyí jẹ́ oríṣi tí ó wọ́pọ̀ jùlọ nínú arun àtọ̀gbẹ. Ara kò pèsè insulini tí ó tó tàbí ṣe ìmúlò rẹ̀ déédé. Arun yi máa únfarahàn lẹ́yìn ọjọ́-orí ogójì (40), b'ótilẹ̀jẹ́pé a tún lè ríi lára àwọn ọmọdé.
Nígbàgbogbo, àwọn àmì àìsàn yí ùnṣẹlẹ̀ díẹ̀díẹ̀ àti pé ó rọrùn láti fojúfòdá.
Tí a bá ti ju ọmọ ogójì ọdún lọ.
Ìsanrajù.
Àìṣe ìdárayá.
Ìtàn ìdílé.
Àtọ̀gbẹ tí o ṣẹlẹ̀ nígbà oyún.
Ẹ̀jẹ̀ ríru.
Àwọn ewu okùnfà àrùn àtọ̀gbẹ oríṣi kejì.
Ewu àrùn àtọ̀gbẹ nínú oyún ga lọ́pọ̀lọpọ̀ láàrín àwọn aboyún tí ó ju ọgbọ̀n ọdún lọ tíwọn sì ní àrùn àtọ̀gbẹ ní ìdílé wọn.
Àtọ̀gbẹ tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà oyún.
Má unwáyé ní díẹ̀ nínú àwọn obìnrin ní àkókò oyún, láàrín oṣù kẹfà sí oṣù kéje. Púpọ̀ jùlọ nínú obìnrin wọ̀nyi lè ní àrùn àtọ̀gbẹ oríṣi kejì ní’jọ́ iwájú. Gbogbo abóyún gbọ́dọ̀ ṣe àyẹ̀wo fún àrùn àtọ̀gbẹ.
Tí o bá ní àrùn ṣuga, béèrè lọ́wọ́ dókítà rẹ fún àyẹ̀wò HbA1c rẹ ní oṣù mẹ́ta mẹ́ta. A fẹ́ kí HbA1c rẹ kó kéré ju ìdá méje nínú ọgọrun- 7% (53 mmol/mol).
Àwọn àmì àìsàn yí.
Haemoglobin A1c jẹ́ àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ tí ó tọ́kasí àpapọ̀ ṣuga ẹjẹ ní oṣù mẹ́ta sẹ́yìn. Nígbàtí ìwọ̀n ṣuga ẹjẹ bá ga, àwọn ṣuga yí á somọ́ awọn sẹ́ẹ́lì ẹjẹ pupa. Èyí ṣe àlékún ìwọ̀n HbA1c.
Àyẹ̀wò àrùn àtọ̀gbẹ.
Ẹ̀jẹ̀ ṣúgà t’ó ṣe déédé:
Kí a tó jẹun àárọ̀ gbọ́dọ̀ kéré ju 5.5 mml/L (100 mg/dl).
Nígbàkúgbà gbọdọ kere ju 7.8 mml/L (140 mg/dl).
Ìbẹ̀rẹ̀ àrùn àtọ̀gbẹ (Pre-diabetes):
Kí a tó jẹun àárọ̀: Láarín 5.5-6.9 mml/L (100-125mg/dl).
Nígbàkúgbà: Láarín 7.8-11 mml/L (140-199 mg/dl).
Arun atọgbẹ:
Kí a tó jẹun àárọ̀: 7 mml/L (126 mg/dl) tàbí jùbẹ́ lọ.
Tàbí
Nígbàkúgbà: 11.1 mml/L (200 mg/dl) tàbí jùbẹ́ lọ
A gbọ́dọ̀ padà ṣe àyẹ̀wò ṣúgà t'ó bá ga ju déédé ní ọjọ́ míràn láti mọ̀ dájú.
Àìtó ṣuga nìnù ẹjẹ (hypoglycemia).
Èyí lè ṣẹlẹ̀ nígbàtí a kò bá jẹ oúnjẹ tàbí jẹun tí kò tó, lo insulínì púpọ̀ tàbí àwọn oògùn tábúlẹ́tì àrùn ṣúgà láì jẹun. Ó máa n sẹlẹ̀ lójijì ó sì lè fa ikú.
Ríi dájú pé o ní oúnjẹ ní iwájú rẹ ṣáájú lílo insulínì tàbí ní àyíká kí o tó mu àwọn oògùn tábúlẹ́tì àrùn àtọ̀gbẹ. Ṣètò àwọn àkókò oúnjẹ́ rẹ ní àwọn ìgbà àtílo oògùn rẹ.
Tí o bá ní àrùn àtọ̀gbẹ tí o sì ní àwọn àmí yí, yára ṣe àyẹ̀wò ṣúgà rẹ. Tí o kò bá lè ṣ’àyẹ̀wò, ṣe ìtọ́jú lọ́nàkọnà nípa jíjẹ àwọn oúnjẹ tàbí ohun mímu tí ó ní ṣúgà.
Ìtọ́jú àrùn àtọ̀gbẹ.
Jòkó pẹ̀lú dókítà rẹ láti jíròrò lórí àṣàyàn ìtọ́jú tí ó dára jùlọ tàbí tí ó tọ́ fún ẹ.
Ìtọ́jú àtọ̀gbẹ lè jẹ́ pẹ̀lú abẹ́rẹ́ insulini tàbí àwọn oògùn tábúlẹ́tì, tàbí méjèjì.
Gbìyànjú láti ṣe eré ìdárayá tàbí iṣẹ́ tí ó lè fa ìlàágùn fún wákàtí kan lójojúmọ́.
Jáwọ́ nínú sìgá mímu.
Yẹra fún ọtí àmujù.
Tọ́jú àrùn ẹ̀jẹ̀ ríru tàbí ọ̀rá ẹ̀jẹ̀ (cholesterol) rẹ.
Àwọn oúnjẹ tí ó dára fún àrun ṣúgà.
Ọbẹ̀: Ẹ̀fọ́ lóríṣiríṣi, ẹ̀gúṣí, ilá, ọ̀gbọ̀nọ̀, edikan ikong, afang, ọbẹ̀ kuka, ọbẹ̀ moringa.
Oúnjẹ òkèlè: Èlùbọ́ ọ̀gẹ̀dẹ̀ dúdú, èlùbọ́ ọkà bàbà, èlùbọ́ jéró.
Àwọn oúnjẹ tí kì únṣe òkèlè: Àṣáró ọ̀gẹ̀dẹ̀ dúdú, mọ́í-mọ́í, àkàrà, ẹ̀wà, bọ̀ọ̀lì, ẹyin, búrẹ́dì alikama, ìrẹsì brown.
Ìpápánu: Akàn, àgbọn, ẹ́pá, pear, wàrànkàṣì.
Ùnkan mímu, tí kò ní ṣúgà: Sóbò, ẹ̀kọ jéró, ẹ̀kọ ọka bàbà, wàrà (milk), yogurt.
Jẹ àwọn èso níwọ̀n nítorí ṣúgà inú wọn. Ṣọ́ra fún mímu oje èso inú ìgò.
O lè yàgò fún gbogbo àwọn ewu àrùn àtọ̀gbẹ àti gbé ìgbésí ayé àlááfíà nípa ìṣàfíyèsí àrùn yí àti ìsowọ́pọ̀ pẹ̀lú dókítà rẹ. Á wà níbí láti ṣe ìrànlọ́wọ́. A fẹ́ kí o mọ̀ pé ìwọ nìkan kọ́ lóní àrùn yí.